Jeremiah 49:10 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ṣugbọn mo ti tú àwọn ọmọ Esau sí ìhòòhò, Mo ti sọ ibi tí wọn ń sápamọ́ sí di gbangba, wọn kò sì rí ibi sápamọ́ sí mọ́. Àwọn ọmọ wọn ti parun, pẹlu àwọn arakunrin wọn ati àwọn aládùúgbò wọn; àwọn pàápàá sì ti di àwátì.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori emi ti tú Esau ni ihoho, emi ti fi ibi ikọkọ rẹ̀ han, on kì o si le fi ara rẹ̀ pamọ; iru-ọmọ rẹ̀ di ijẹ, ati awọn arakunrin rẹ̀, ati awọn aladugbo rẹ̀, nwọn kò sí mọ́.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n èmi yóò tu Ísọ̀ sí ìhòòhò èmi kò ní bo ibi ìkọ̀kọ rẹ nítorí kí o máa baà fi ara rẹ pamọ́. Àwọn ọmọ rẹ, ẹbí rẹ àti àwọn ará ilé rẹ yóò parun. Wọn kò sì ní sí mọ́.