Jeremiah 49:13 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nítorí pé mo ti fi ara mi búra, èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀, pé Bosira yóo di àríbẹ̀rù ati ohun ẹ̀gàn, ahoro ati ohun àmúgégùn-ún; àwọn ìlú rẹ̀ yóo sì di ahoro títí lae.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori emi ti fi ara mi bura, li Oluwa wi pe: Bosra yio di ahoro, ẹ̀gan, idahoro, ati egún; ati gbogbo ilu rẹ̀ ni yio di ahoro lailai.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èmi fi ara mi búra ni OLÚWA wí, wí pé, “Bósírà yóò bayé ara rẹ̀ jẹ́. Yóò di ẹni ẹ̀gàn, ẹni èpè àti ẹni ẹgún, àti gbogbo ìlú rẹ̀ yóò di ìbàjẹ́ títí láé.”