Jeremiah 49:14 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Mo ti gbọ́ ìròyìn láti ọ̀dọ̀ OLUWA, wọ́n ti rán ikọ̀ kan sí àwọn orílẹ̀-èdè, wọ́n ní kí wọn kéde pé, “OLUWA ní, ‘Ẹ kó ara yín jọ, kí ẹ kọlu Edomu, ẹ dìde, kí ẹ gbógun tì í!
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ni gbigbọ́ emi ti gbọ́ iró lati ọdọ Oluwa wá, a si ran ikọ̀ si awọn orilẹ-ède pe, ẹ kó ara nyin jọ, ẹ wá sori rẹ̀, ẹ si dide lati jagun.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èmi ti gbọ́ ọ̀rọ̀ kan láti ọ̀dọ̀ OLÚWA: A rán ikọ̀ kan sí orílẹ̀ èdè láti sọ. Ẹ kó ara yín jọ láti dojúkọ ọ́, ẹ dìde fún ogun.