Jeremiah 49:18 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Yóo rí fún un bí ó ti rí fún Sodomu ati Gomora ati àwọn ìlú agbègbè wọn tí ó parun. Ẹnikẹ́ni kò ní gbé ibẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ẹnikẹ́ni kò ní dé sibẹ. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Gẹgẹ bi ni ibiṣubu Sodomu ati Gomorra ati awọn aladugbo rẹ̀, li Oluwa wi; ẹnikan kì yio gbe ibẹ mọ, bẹ̃ni ọmọ enia kan kì yio ṣatipo ninu rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe gba Sódómù àti Gòmórà pẹ̀lú àwọn ìlú tí ó wà ní àyíká rẹ,” ní OLÚWA wí. “Bẹ́ẹ̀ ni, kò sí ẹnikẹ́ni tí yóò gbé níbẹ̀; kò sì ní sí ènìyàn tí yóò tẹ̀dó síbẹ̀ mọ́.