Jeremiah 49:19 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Wò ó, bí kinniun tií yọ ní aginjù odò Jọdani láti kọlu agbo aguntan, bẹ́ẹ̀ ni n óo yọ sí Edomu n óo sì mú kí ó sá kúrò lórí ilẹ̀ rẹ̀ lójijì. N óo sì yan ẹnikẹ́ni tí ó bá wù mí láti máa ṣe àkóso ibẹ̀; nítorí ta ló dàbí mi? Ta ló lè yẹ̀ mí lọ́wọ́ wò? Olùṣọ́-aguntan wo ló lè dúró dè mí?
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Wò o, yio goke wá bi kiniun lati igberaga Jordani si ibugbe okuta; nitori lojiji ni emi o lé wọn jade kuro nibẹ, ati tani ayanfẹ na ti emi o yàn sori rẹ̀, nitori tani dabi emi, tani yio si pè mi ṣe ẹlẹri? ati tani oluṣọ-agutan na, ti yio le duro niwaju mi?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Bí kìnnìún ti ń bọ̀ láti igbó Jódánì wá sí pápá oko ọlọ́rà á èmi yóò lé Édómù láti ibi ilẹ̀ rẹ̀ ní kíákíá. Ta ni ẹni náà tí èmi yóò yàn fún èyí? Ta lo dàbí èmi, ta ni ó le pè mí níjà? Ta ni olùsọ́ àgùntàn náà tí ó lè dúró níwájú mi?”