Jeremiah 49:2 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nítorí náà, wò ó, àkókò ń bọ̀ tí n óo jẹ́ kí ariwo ogun sọ, ní Raba ìlú àwọn ọmọ Amoni; Raba yóo di òkítì àlàpà, a óo sì dáná sun àwọn ìgbèríko rẹ̀; Israẹli yóo wá pada fi ogun kó àwọn tí wọ́n kó o lẹ́rú.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitorina, wò o, ọjọ mbọ̀, li Oluwa wi, ti emi o mu ki a gbọ́ idagiri ogun ni Rabba ti awọn ọmọ Ammoni: yio si di okiti ahoro, a o si fi iná sun awọn ọmọbinrin rẹ̀; nigbana ni Israeli yio jẹ arole awọn ti o ti jẹ arole rẹ̀, li Oluwa wi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n ọjọ́ náà ń bọ̀,” ni OLÚWA wí; “nígbà tí èmi yóò mú ìdágìrì ogun bá Rábà tí Ámónì yóò sì di òkítì ahoro, gbogbo ìlú tí ó yí i ká ni a ó jó níná. Nígbà náà ni Ísírẹ́lì yóò lé wọn, àwọn tí ó ti lé e jáde,” ni OLÚWA wí.