Jeremiah 49:20 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nítorí náà, ẹ gbọ́ ète tí OLUWA pa lórí Edomu, ati èrò rẹ̀ lórí àwọn tí wọn ń gbé Temani. A óo kó agbo ẹran wọn lọ tọmọtọmọ, ibùjẹ àwọn ẹran wọn yóo parun nítorí tiwọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitorina gbọ́ ìmọ Oluwa ti o ti gbà si Edomu; ati èro rẹ̀ ti o ti gba si awọn olugbe Temani pe, Lõtọ awọn ẹniti o kere julọ ninu agbo-ẹran yio wọ́ wọn kiri, lõtọ nwọn o sọ buka wọn di ahoro lori wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí náà, ẹ gbọ́ ohun tí OLÚWA ní fún Édómù, ohun tí ó ní ní pàtàkì fún àwọn tí ń gbé ní Témánì. Àwọn ọ̀dọ́ àgbò ni à ó lé jáde. Pápá oko wọn ni yóò run nítorí wọn.