Jeremiah 49:3 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn, ìwọ Heṣiboni, nítorí pé ìlú Ai ti parun! Ẹ sọkún, ẹ̀yin ọmọbinrin Raba! Ẹ ró aṣọ ọ̀fọ̀, ẹ máa sọkún, kí ẹ sì máa sá sókè sódò láàrin ọgbà! Nítorí pé oriṣa Moleki yóo lọ sí ìgbèkùn, pẹlu àwọn babalóòṣà rẹ̀ ati àwọn ìjòyè ní ibi ìsìn rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Hu, iwọ Heṣboni! nitori a fi Ai ṣe ijẹ: kigbe, ẹnyin ọmọbinrin Rabba! ẹ di aṣọ-ọ̀fọ mọra, ẹ pohunrere, ki ẹ si sare soke-sodo lãrin ọgba! nitori Malkomu yio jumọ lọ si igbekun, awọn alufa rẹ̀ ati awọn ijoye rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Pohùnréré ẹkún ìwọ Hésíbónì nítorí Áì tí rún, kígbe jáde ẹ̀yin ènìyàn Rábà, ẹ wọ aṣọ ọ̀fọ̀ kí ẹ sì ṣọ̀fọ̀. Ẹ sáré sókè sódò nínú ọgbà nítorí Mákómù yóò lọ sí ìgbèkùn pẹ̀lú àwọn àlùfáà àti ìjòyè rẹ̀.