Jeremiah 49:32 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
“Àwọn ràkúnmí ati agbo ẹran wọn yóo di ìkógun. N óo fọ́n àwọn tí wọn ń gé ẹsẹ̀ irun wọn ká sí igun mẹrẹẹrin ayé, n óo sì mú kí ibi bá wọn láti gbogbo àyíká wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ibakasiẹ wọn yio si di ikogun, ati ọ̀pọlọpọ ẹran-ọ̀sin wọn yio di ijẹ: emi o si tú awọn ti nda òṣu ka si gbogbo ọ̀na afẹfẹ; emi o si mu wahala wọn de lati iha gbogbo, li Oluwa wi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn ràkunmí á di ẹrù àti àwọn agbo àgùntàn, wọ́n á di ìkógun. Èmi yóò tú àwọn tí ó wà ní òkèèrè sí inú afẹ́fẹ́. Èmi yóò sì mú ibi wá sí àyíká gbogbo,” báyìí ní OLÚWA wí.