Jeremiah 49:37 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
N óo dẹ́rùbà wọ́n; níwájú àwọn ọ̀tá wọn, ati níwájú àwọn tí ń wá ọ̀nà ati pa wọ́n. N óo bínú sí wọn gan-an, n óo sì mú kí ibi dé bá wọn. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀. N óo rán ogun tẹ̀lé wọn, títí n óo fi pa wọ́n tán.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori emi o mu Elamu warìri niwaju awọn ọta wọn, ati niwaju awọn ti nwá ẹmi wọn: emi o si mu ibi wá sori wọn, ani ibinu gbigbona mi, li Oluwa wi; emi o si rán idà tẹle wọn, titi emi o fi run wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èmi yóò kẹ́gàn Élámù lójú àwọn ọ̀tá rẹ̀ àti lọ́dọ̀ àwọn tí wọ́n jọ ń gbé. Èmi yóò mú ibi wá sí orí wọn, pàápàá ìbínú gbígbóná mi;” bẹ́ẹ̀ ni OLÚWA wí. “Èmi yóò lé wọn pẹ̀lú idà, di ìgbà tí èmi yóò rẹ́yìn wọn.