Jeremiah 49:7 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ohun tí OLUWA àwọn ọmọ ogun sọ nípa Edomu nìyí: Ó ní, “Ṣé kò sí ọgbọ́n ní Temani mọ́ ni? Àbí àwọn amòye kò ní ìmọ̀ràn lẹ́nu mọ́? Ṣé ọgbọ́n ti rá mọ́ wọn ninu ni?
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Si Edomu. Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi; Kò ha si ọgbọ́n mọ ni Temani? a ha ke imọran kuro lọdọ oloye? ọgbọ́n wọn ha danu bi?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nípa Édómù: Èyí ní ohun tí OLÚWA àwọn ọmọ ogun wí: “Ṣe kò ha sí ọgbọ́n mọ́ ni Temánì? Ṣé a ti ké ìmọ̀ràn kúrò ní ọ̀dọ̀ olóyè? Ṣé ọgbọ́n wọn ti bàjẹ́ bí?