Jeremiah 49:8 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ẹ̀yin ará Dedani, ẹ pada kíá, ẹ máa sálọ. Ẹ wọ inú ihò lọ, kí ẹ lọ máa gbébẹ̀! Nítorí pé ní ìgbà tí mo bá jẹ ìran Esau níyà, n óo mú kí ibi dé bá wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ẹ sa, ẹ yipada, ẹ ṣe ibi jijin lati ma gbe ẹnyin olugbe Dedani; nitori emi o mu wahala Esau wá sori rẹ̀, àkoko ti emi o bẹ̀ ẹ wò.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Yípadà kí o sálọ, sá pamọ́ sínú ihò, ìwọ tí ó ń gbé ní Dédánì nítorí èmi yóò mú ibi wá sórí Ísọ̀ ní àkókò tí èmi ó fìyà jẹ́ẹ́.