Jeremiah 5:10 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Kọjá lọ láàrin ọgbà àjàrà rẹ̀ ní poro ní poro, kí o sì pa á run, ṣugbọn má ṣe pa gbogbo rẹ̀ run tán. Gé àwọn ẹ̀ka rẹ̀ kúrò, nítorí pé wọn kì í ṣe ti OLUWA.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ẹ goke lọ si ori odi rẹ̀, ki ẹ si parun; ṣugbọn ẹ máṣe pa a run tan: ẹ wó kùrùkúrù rẹ̀ kuro nitori nwọn kì iṣe ti Oluwa.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Lọ sí ọgbà àjàrà rẹ̀, kí ẹ sì pa wọ́n run, ẹ má ṣe pa wọ́n run pátapáta. Ya ẹ̀ka rẹ̀ kúrò, nítorí àwọn ènìyàn wọ̀nyí kì í ṣe ti OLÚWA.