Jeremiah 5:12 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Àwọn eniyan yìí ti sọ ọ̀rọ̀ èké nípa OLUWA, wọ́n ní, “OLUWA kọ́! Kò ní ṣe nǹkankan; ibi kankan kò ní dé bá wa, bẹ́ẹ̀ ni a kò ní rí ogun tabi ìyàn.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn sẹ Oluwa, wipe, Kì iṣe on, ibi kò ni wá si ori wa, awa kì yio si ri idà tabi ìyan:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wọ́n ti pa irọ́ mọ́ OLÚWA; wọ́n wí pé, “Òun kì yóò ṣe ohun kan! Ibi kan kì yóò sì tọ̀ wá wá; àwa kì yóò sì rí idà tàbí ìyàn.