Jeremiah 5:14 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nítorí náà, OLUWA Ọlọrun àwọn ọmọ ogun ní, “Nítorí ohun tí wọ́n sọ yìí, wò ó, n óo jẹ́ kí ọ̀rọ̀ mi di iná lẹ́nu rẹ. N óo sì jẹ́ kí àwọn eniyan wọnyi dàbí igi, iná yóo sì jó wọn run.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitorina bayi li Oluwa, Ọlọrun awọn ọmọ-ogun wi, nitori ẹnyin sọ ọ̀rọ yi, sa wò o, emi o sọ ọ̀rọ mi li ẹnu rẹ di iná, ati awọn enia yi di igi, yio si jo wọn run.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí náà, báyìí ni OLÚWA Ọlọ́run alágbára wí: “Nítorí tí àwọn ènìyàn ti sọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí; Èmi yóò sọ ọ̀rọ̀ mi lẹ́nu wọn di iná, àti àwọn ènìyàn wọ̀nyí di igi tí yóò jórun.