Jeremiah 5:15 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ẹ wò ó, ẹ̀yin ọmọ ilé Israẹli, mò ń mú orílẹ̀-èdè kan bọ̀ wá ba yín, láti ilẹ̀ òkèèrè, tí yóo ba yín jà. Láti ayé àtijọ́ ni orílẹ̀-èdè ọ̀hún ti wà, orílẹ̀-èdè alágbára ni. Ẹ kò gbọ́ èdè wọn, ẹ kò sì ní mọ ohun tí wọ́n ń sọ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Wò o emi o mu orilẹ-ède kan wá sori nyin lati ọ̀na jijin, ẹnyin ile Israeli, li Oluwa wi, orilẹ-ède alagbara ni, orilẹ-ède lati igbãni wá ni, orilẹ-ède ti iwọ kò mọ̀ ede rẹ̀, bẹ̃ni iwọ kò gbọ́ eyiti o nwi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Áà, ẹ̀yin ilé Ísírẹ́lì,” ni OLÚWA wí, “Èmi yóò mú kí orílẹ̀ èdè láti ọ̀nà jínjìn dìde sí i yín Orílẹ̀ èdè ìgbàanì àti alágbára nì àwọn ènìyàn tí ìwọ kò mọ èdè rẹ̀, tí ọ̀rọ̀ rẹ̀ kò sì yé ọ.