Jeremiah 5:17 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Wọn yóo jẹ yín ní oúnjẹ, wọn yóo sì kó gbogbo ìkórè oko yín lọ, wọn yóo run àwọn ọmọ yín lọkunrin ati lobinrin. Wọn yóo run ẹran ọ̀sìn yín, ati àwọn mààlúù yín. Wọn yóo run èso ọgbà àjàrà yín, ati igi ọ̀pọ̀tọ́ yín. Idà ni wọn yóo fi pa àwọn ìlú olódi yín tí ẹ gbẹ́kẹ̀lé run.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
On o si jẹ ikore rẹ ati onjẹ rẹ, nwọn o jẹ awọn ọmọkunrin ati awọn ọmọbinrin rẹ, nwọn o si jẹ agbo rẹ ati ọwọ́-ẹran rẹ, nwọn o jẹ àjara rẹ ati igi ọ̀pọtọ rẹ, nwọn o fi idà sọ ilu olodi rẹ ti iwọ gbẹkẹle di ahoro.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wọn yóò jẹ ìkórè rẹ àti oúnjẹ rẹ, àwọn ọmọ rẹ ọkùnrin àti obìnrin, wọn yóò sì jẹ agbo àti ẹran rẹ, wọn yóò jẹ àjàrà àti igi ọ̀pọ̀tọ́ rẹ. Pẹ̀lú idà ni wọn ó run ìlú tí ìwọ gbẹ́kẹ̀lé.”