Jeremiah 5:19 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
nígbà tí àwọn eniyan bá bèèrè pé, ‘Kí ló dé tí OLUWA Ọlọrun wa fi ṣe gbogbo nǹkan wọnyi sí wa?’ Ẹ óo le dá wọn lóhùn pé bí ẹ ṣe kọ èmi OLUWA sílẹ̀, tí ẹ sì ń bọ oriṣa àjèjì ní ilẹ̀ yín, bẹ́ẹ̀ ni ẹ óo ṣe sin àwọn àjèjì ní ilẹ̀ tí kì í ṣe tiyín.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Yio si ṣe, nigbati ẹnyin o wipe: Ẽṣe ti Oluwa Ọlọrun wa fi ṣe gbogbo ohun wọnyi si wa? nigbana ni iwọ o da wọn lohùn: Gẹgẹ bi ẹnyin ti kọ̀ mi, ti ẹnyin si nsìn ọlọrun ajeji ni ilẹ nyin, bẹ̃ni ẹnyin o sin alejo ni ilẹ ti kì iṣe ti nyin.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àti pé, nígbà tí àwọn ènìyàn bá sì béèrè wí pé, ‘Kí ni ìdí rẹ̀ tí OLÚWA Ọlọ́run wa fi ṣe gbogbo èyí sí wa?’ Ìwọ yóò sì sọ fún wọn wí pé, ‘Ẹ̀yin ti kọ̀mí sílẹ̀, ẹ sì ń sin Ọlọ́run àjèjì ní ilẹ̀ yín. Nísinsìnyìí, ẹ̀yin yóò máa sin àjèjì ní ilẹ̀ tí kì í ṣe ti yín.’