Jeremiah 5:22 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ẹ̀rù mi kò tilẹ̀ bà yín? Èmi OLUWA ni mò ń bi yín léèrè. Ẹ wà níwájú mi ẹ kò máa gbọ̀n pẹ̀pẹ̀. Èmi tí mo fi iyanrìn pààlà fún omi òkun, tí òkun kò sì gbọdọ̀ rékọjá rẹ̀ títí ayé! Bí ó tilẹ̀ ń ru sókè, kò lágbára kan, kí ìgbì rẹ̀ máa hó yaya, kò lè kọjá ààlà náà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ẹ kò ha bẹ̀ru mi; li Oluwa wi, ẹ kì yio warìri niwaju mi, ẹniti o fi yanrin ṣe ipãla okun, opin lailai ti kò le rekọja: ìgbì rẹ̀ kọlu u, kò si le bori rẹ̀, o pariwo, ṣugbọn kò lè re e kọja?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Kò ha yẹ kí ẹ bẹ̀rù mi?” ni OLÚWA wí. “Kò ha yẹ kí èyin ó wárìrì níwájú mi bí? Mo fi yanrìn pààlà òkun, èyí tí kò le è rékọjá rẹ̀ láéláé. Ìjì lè jà, kò le è borí rẹ̀; wọ́n le è bú, wọn kò le è rékọjá rẹ̀.