Jeremiah 5:28 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
wọ́n sanra, ara wọn sì ń dán. Ṣugbọn iṣẹ́ ibi wọn kò ní ààlà. Wọn kìí dá ẹjọ́ ẹ̀tọ́ fún aláìníbaba, kí ó lè rí ẹ̀tọ́ rẹ̀ gbà; wọn kò sì jẹ́ gbèjà aláìní, kí wọ́n bá a dáàbò bo ẹ̀tọ́ rẹ̀ nílé ẹjọ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn sanra, nwọn ndán, pẹlupẹlu nwọn rekọja ni ìwa-buburu, nwọn kò ṣe idajọ, nwọn kò dajọ ọ̀ran alainibaba, ki nwọn le ri rere; nwọn kò si dajọ are awọn talaka.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wọ́n sanra wọ́n sì dán. Ìwà búburú wọn kò sì lópin; wọn kò bẹ̀bẹ̀ fún ẹjọ́ àwọn aláìní baba láti borí rẹ̀. Wọn kò jà fún ẹ̀tọ́ àwọn tálákà.