Jeremiah 5:3 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
OLUWA, ṣebí òtítọ́ ni ò ń fẹ́? Ò ń nà wọ́n ní pàṣán, ṣugbọn kò dùn wọ́n, o tẹ̀ wọ́n ní àtẹ̀rẹ́, ṣugbọn wọn kò gbọ́ ìbáwí. Ojú wọn ti dá, ó le koko, wọ́n kọ̀, wọn kò ronupiwada.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Oluwa, oju rẹ kò ha wà lara otitọ? iwọ ti lù wọn, ṣugbọn kò dùn wọn; iwọ ti run wọn, ṣugbọn nwọn kọ̀ lati gba ẹkọ: nwọn ti mu oju wọn le jù apata lọ; nwọn kọ̀ lati yipada.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
OLÚWA, ojú rẹ kò ha wà lára òtítọ́ Ìwọ lù wọ́n, kò dùn wọ́n. Ìwọ bá wọn wí, wọ́n kọ̀ láti yípadà. Wọ́n mú ojú wọn le ju òkúta lọ, wọ́n sì kọ̀ láti yípadà.