Jeremiah 5:6 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nítorí náà, kinniun inú igbó ni yóo wá kì wọ́n mọ́lẹ̀. Ìkookò inú aṣálẹ̀ ni yóo wá jẹ wọ́n run. Àmọ̀tẹ́kùn yóo ba dè wọ́n ní àwọn ìlú wọn, tí ẹnikẹ́ni bá jáde ní ìlú, yóo fà á ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ. Nítorí pé ẹ̀ṣẹ̀ wọn pọ̀, nígbà pupọ ni wọ́n sì ti yipada kúrò ní ọ̀nà Ọlọrun.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitorina kiniun lati inu igbo wa yio pa wọn, ikõko aṣálẹ̀ yio pa wọn run, ẹkùn yio mã ṣọ ilu wọn: ẹnikẹni ti o ba ti ibẹ jade li a o ya pẹrẹpẹrẹ: nitori ẹ̀ṣẹ wọn pọ̀, ati ipẹhinda wọn le.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí náà, kìnnìún láti inú igbó yóò kọlù wọ́n, ìkokò ihà yóò sì pa wọ́n run, ẹkùn yóò máa ṣe ibùba sí ẹ̀bá ìlú yín ẹnikẹ́ni tí ó bá jáde ni yóò fàya pẹ́rẹpẹ̀rẹ, nítorí àìgbọ́ràn yín pọ, apadàsẹ́yìn wọn sì pọ̀.