Jeremiah 5:7 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
OLUWA bi Israẹli pé, “Báwo ni mo ṣe lè dárí ẹ̀ṣẹ̀ jìn ọ́? Àwọn ọmọ rẹ ti kọ̀ mí sílẹ̀, wọ́n sì ti ń fi àwọn ohun tí kì í ṣe ọlọrun búra. Nígbà tí mo bọ́ wọn ní àbọ́yó tán, wọ́n ṣe àgbèrè, wọ́n dà lọ sí ilé àwọn alágbèrè.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Emi o ha ṣe dari eyi ji ọ? awọn ọmọ rẹ ti kọ̀ mi silẹ, nwọn si fi eyi ti kì iṣe ọlọrun bura: emi ti mu wọn bura, ṣugbọn nwọn ṣe panṣaga, nwọn si kó ara wọn jọ si ile àgbere.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Kí ni ṣe tí èmi ó ṣe dáríjì ọ́? Àwọn ọmọ rẹ ti kọ̀ mí sílẹ̀ àti pé wọ́n ti fi ọlọ́run tí kì í ṣe Ọlọ́run búra. Mo pèṣè fún gbogbo àìní wọn, síbẹ̀ wọ́n tún ń ṣe panṣágà wọ́n sì kórajọ sí ilé àwọn alágbérè.