Jeremiah 50:11 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
OLUWA ní, “Ẹ̀yin ará Babiloni, tí ẹ kó àwọn eniyan mi, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé inú yín dùn ẹ sì ń yọ̀, tí ẹ sì ń ṣe ojúkòkòrò, bí akọ mààlúù tí ń jẹko ninu pápá, tí ẹ sì ń yan bí akọ ẹṣin:
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitoripe inu nyin dùn, nitoripe ẹnyin yọ̀, ẹnyin olè ti o ji ini mi, nitori ti ẹnyin fi ayọ̀ fò bi ẹgbọrọ malu si koriko tutu, ẹ si nyán bi akọ-ẹṣin:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Nítorí pé inú yín dùn nítorí pé ẹ̀yìn yọ̀, ẹ̀yìn olè tí ó jí ìní mi, nítorí tí ẹ̀yìn fi ayọ̀ fò bí ẹgbọ̀rọ̀ màlúù sí koríko tútù, ẹsì ń yan bí akọ-ẹsin.