Jeremiah 50:12 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ojú yóo ti olú-ìlú yín lọpọlọpọ, a óo dójú ti ilẹ̀ ìbí yín. Wò ó! Yóo di èrò ẹ̀yìn láàrin àwọn orílẹ̀-èdè, yóo di aṣálẹ̀ tí ó gbẹ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Oju yio tì iya nyin pupọpupọ; itiju yio bo ẹniti o bi nyin: wò o, ikẹhin awọn orilẹ-ède! aginju, ilẹ gbigbẹ, ati ahoro!
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ojú yóò ti ìyá rẹ, ẹni tí ó bí ọ yóò sì gba ìtìjú. Òun ni yóò jẹ́ kékeré jù nínú àwọn orílẹ̀ èdè, ilẹ̀ aṣálẹ̀ àti ihà tí kò lọ́ràá.