Jeremiah 50:13 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nítorí ibinu gbígbóná OLUWA, ẹnikẹ́ni kò ní gbé ibẹ̀ mọ́; yóo di ahoro patapata; ẹnu yóo ya gbogbo ẹni tí ó bá gba Babiloni kọjá, wọn yóo sì máa pòṣé nítorí ìyà tí a fi jẹ ẹ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori ibinu Oluwa li a kì yio gbe inu rẹ̀, ṣugbọn yio dahoro patapata: olukuluku ẹniti o ba re Babeli kọja yio yanu, yio si ṣe ẹlẹya si gbogbo ipọnju rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí ìbínú OLÚWA, kì yóò ní olùgbé; ẹnikẹ́ni kò sì ní gbé inú rẹ̀. Gbogbo àwọn tí ó bá kọjá ni Bábílónì yóò fi ṣe yẹ̀yẹ́ nítorí ọgbẹ́ rẹ̀.