Jeremiah 50:15 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Gbogbo ẹ̀yin tí ẹ yí i ká, ẹ hó bò ó, ó ti jọ̀wọ́ ara rẹ̀ sílẹ̀. Àwọn ibi ààbò rẹ̀ ti wó, àwọn odi rẹ̀ sì ti wó lulẹ̀. Nítorí ẹ̀san OLUWA ni, ẹ gbẹ̀san lára rẹ̀; ẹ ṣe sí i bí òun náà ti ṣe sí àwọn ẹlòmíràn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ẹ ho bo o yikakiri: o ti nà ọwọ rẹ̀: ọwọ̀n ìti rẹ̀ ṣubu, a wó odi rẹ̀ lulẹ: nitori igbẹsan Oluwa ni: ẹ gbẹsan lara rẹ̀; gẹgẹ bi o ti ṣe, ẹ ṣe bẹ̃ si i.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Kígbe mọ-ọn ní gbogbo ọ̀nà! Ó tẹríba, òpó rẹ̀ sì yẹ̀, níwọ̀n ìgbà tí ó ti jẹ́ wí pé èyí ni ìgbẹ̀san OLÚWA, gbẹ̀san lára rẹ̀. Ṣe síi gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe sí àwọn ẹlòmìíràn.