Jeremiah 50:16 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ẹ pa àwọn afunrugbin run ní Babiloni, ati àwọn tí ń lo dòjé ní ìgbà ìkórè. Olukuluku yóo pada sọ́dọ̀ àwọn eniyan rẹ̀, yóo sì sá pada sí ilẹ̀ rẹ̀, nítorí idà àwọn aninilára.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ke afunrugbin kuro ni Babeli, ati ẹniti ndi doje mu ni igbà ikore! nitori ẹ̀ru idà ti nṣika, olukuluku wọn o yipada si ọdọ enia rẹ̀, olukuluku yio si salọ si ilẹ rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Mú kúrò ní Bábílónì olùgbìn àti olùkórè pẹ̀lú ohun ìkórè rẹ̀. Nítorí idà àwọn aninilára jẹ́ kí oníkálùkù padà sí ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn rẹ̀, kí oníkálukú sì sá padà sí ilẹ̀ rẹ̀.