Jeremiah 50:2 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
“Kéde láàrin àwọn orílẹ̀-èdè, ta àsíá, kí o sì kéde. Má fi ohunkohun pamọ́; sọ pé, ‘Ogun tí kó Babiloni, ojú ti oriṣa Bẹli, oriṣa Merodaki wà ninu ìdààmú. Ojú ti àwọn ère rẹ̀, ìdààmú sì bá wọn.’
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ẹ sọ ọ lãrin awọn orilẹ-ède, ẹ si kede, ki ẹ si gbe asia soke: ẹ kede, ẹ má si ṣe bò o: wipe, a kó Babeli, oju tì Beli, a fọ Merodaki tutu; oju tì awọn ere rẹ̀, a fọ awọn òriṣa rẹ̀ tutu.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Ẹ sọ ọ́ láàrin àwọn orílẹ̀-èdè, ẹ sì kéde, kí ẹ sì gbé àṣíà sókè. Ẹ kede, ẹ má sì ṣe bòó wí pé, ‘a kó Bábílónì, ojú tí Bélì, a fọ́ Merodákì túútúú, ojú ti àwọn ère rẹ̀, a fọ́ àwọn òrìṣà rẹ̀ túútúú.’