Jeremiah 50:23 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ẹ wo bí a ti gé òòlù tó ti ń lu gbogbo ayé lulẹ̀, tí a sì fọ́ ọ! Ẹ wo bí Babiloni ti di ohun àríbẹ̀rù, láàrin àwọn orílẹ̀-èdè.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bawo li a ti fọ, ti a si ṣẹ olú gbogbo ilẹ aiye! Bawo ni Babeli di ahoro lãrin awọn orilẹ-ède!
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wo bi ilé ayé ti pín sí wẹ́lẹ́wẹ́lẹ́ tó. Wo bí Bábílónì ti di aláìlólùgbé ni àárin àwọn orílẹ̀ èdè.