Jeremiah 50:24 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Mo dẹ tàkúté sílẹ̀ fun yín, ẹ̀yin ará Babiloni: Tàkúté náà mu yín, ẹ kò sì mọ̀. Wọ́n ri yín, ọwọ́ sì tẹ̀ yín, nítorí pé ẹ yájú sí èmi OLUWA.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Emi ti kẹ okùn fun ọ, a si mu ọ, iwọ Babeli, iwọ kò si mọ̀: a ri ọ, a si mu ọ pẹlu, nitoripe iwọ ti ba Oluwa ja.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Mo dẹ pàkúté sílẹ̀ fún ọ ìwọ Bábílónì, kí o sì tó mọ ohun tí ó ń ṣẹlẹ̀, o ti kó sínú rẹ̀. A mú ọ nítorí pé o tako OLÚWA.