Jeremiah 50:28 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
(Ẹ gbọ́ ariwo bí àwọn eniyan tí ń sá àsálà kúrò ní ilẹ̀ Babiloni, wá sí Sioni, láti wá ròyìn ìgbẹ̀san Ọlọrun wa, ẹ̀san tẹmpili rẹ̀ tí wọ́n wó lulẹ̀.)
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ohùn awọn ti o salọ, ti o si sala lati ilẹ Babeli wá, lati kede igbẹsan Oluwa Ọlọrun wa ni Sioni, igbẹsan tempili rẹ̀!
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Tẹ́tí sí àwọn tí ó sálọ tí ó sì sálà láti Bábílónì, sì sọ ní Síónì, bí OLÚWA Ọlọ́run wa ti gbẹ̀san, ẹ̀san fún tẹ́ḿpílì rẹ̀.