Jeremiah 50:29 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
“Ẹ pe àwọn tafàtafà jọ, kí wọn dojú kọ Babiloni; kí gbogbo àwọn tí wọn ń tafà pàgọ́ yí i ká, kí wọn má jẹ́ kí ẹnikẹ́ni sá àsálà. Ẹ san án fún un gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀, ẹ ṣe sí i bí ó ti ṣe sí àwọn ẹlòmíràn; nítorí pé ó ṣe àfojúdi sí OLUWA, Ẹni Mímọ́ Israẹli.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Pè ọ̀pọlọpọ enia, ani gbogbo tafatafa, sori Babeli, ẹ dótì i yikakiri; má jẹ ki ẹnikan sala: san fun u gẹgẹ bi iṣẹ rẹ̀; gẹgẹ bi gbogbo eyi ti o ti ṣe, ẹ ṣe bẹ̃ si i, nitoriti o ti gberaga si Oluwa, si Ẹni-Mimọ Israeli.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Pe ọ̀pọ̀lopọ̀ ènìyàn, àní gbogbo tafàtafà, sórí Bábílónì, ẹ doti iyikakiri, ma jẹ́ ki ẹnikẹ́ni sálà. Sán fún un gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bi gbógbó èyí ti o ti ṣé, ẹ ṣe bẹ́ẹ̀ síi, nítorí tí ó ti gberaga sí OLÚWA, sí Ẹni-MÍMỌ̀ Ísirẹ́lì.