Jeremiah 50:3 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
“Nítorí pé orílẹ̀-èdè kan láti ìhà àríwá ti gbógun tì í, yóo sọ ilẹ̀ rẹ̀ di ahoro, kò sì ní sí ẹni tí yóo gbé inú rẹ̀ mọ́, ati eniyan ati ẹranko, wọn óo sá kúrò níbẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori lati ariwa ni orilẹ-ède kan ti wá sori rẹ̀, ti yio sọ ilẹ rẹ̀ di ahoro, ẹnikan kì o gbe inu rẹ̀: nwọn o sa, nwọn o lọ, ati enia ati ẹranko.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn ìlú ní apá àríwá yóò sì máa gbógun tì wọ́n. Gbogbo àwọn ènìyàn àti ẹranko ni yóò sá kúrò ní ìlú yìí.