Jeremiah 50:31 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
“Wò ó! Mo dojú kọ ọ́, ìwọ onigbeeraga yìí, nítorí pé ọjọ́ ti pé tí n óo jẹ ọ́ níyà. Èmi OLUWA, Ọlọrun àwọn ọmọ ogun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Wò o, emi dojukọ ọ! iwọ agberaga, li Oluwa, Ọlọrun awọn ọmọ-ogun, wi: nitori ọjọ rẹ de, àkoko ti emi o bẹ̀ ọ wò.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Wò ó, èmi lòdì sí àwọn onígbéraga,” ni OLÚWA Ọlọ́run, “ọmọ ogun wí, nítorí ọjọ́ rẹ ti dé tí ìwọ yóò jìyà.