Jeremiah 50:34 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ṣugbọn alágbára ni Olùràpadà wọn, OLUWA àwọn ọmọ ogun ni orúkọ rẹ̀. Dájúdájú, yóo jà fún wọn, kí ó lè fún ayé ní ìsinmi, ṣugbọn kí ìdààmú lè bá àwọn ará Babiloni.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn Olurapada wọn lagbara; Oluwa awọn ọmọ-ogun li orukọ rẹ̀: ni jijà yio gba ijà wọn jà! ki o le mu ilẹ na simi, ki o si mu awọn olugbe Babeli wariri.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Síbẹ̀, Olùràpadà wọn, Alágbára, OLÚWA Ọlọ́run alágbára ni orúkọ rẹ̀. Yóò sì gbe ìjà wa jà, kí ó ba à lè mú wọn wá sinmí ní ilẹ̀ náà; àmọ́ kò sí ìsinmi fún àwọn tí ó ń gbé Bábílónì.