Jeremiah 50:36 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Idà ni yóo pa àwọn awoṣẹ́ wọn, kí wọ́n lè di òpè! Idà ni yóo pa àwọn ọmọ ogun wọn, kí wọ́n lè parẹ́!
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Idà lori awọn ahalẹ nwọn o si ṣarán: idà lori awọn alagbara rẹ̀; nwọn o si damu.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Idà lórí àwọn wòlíì èké wọn yóò di òmùgọ̀! Idà lórí àwọn jagunjagun, wọn yóò sì kún fún ẹ̀rù.