Jeremiah 50:40 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Yóo dàbí ìgbà tí Ọlọrun pa Sodomu ati Gomora run, pẹlu àwọn ìlú tí ó yí wọn ká; nítorí náà ẹnikẹ́ni kò ní gbé ibẹ̀ mọ́, bẹ́ẹ̀ ni eniyan kò ní máa dé sibẹ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Gẹgẹ bi Ọlọrun ti bì Sodomu ati Gomorra ṣubu ati awọn aladugbo rẹ̀, li Oluwa wi; bẹ̃ni enia kan kì o gbe ibẹ, tabi ọmọ enia kan kì o ṣatipo ninu rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Gẹ́gẹ́ bí OLÚWA ti gba ìjọba Sódómù àti Gòmórà pẹ̀lú àwọn ìlú agbégbé wọn,” ni OLÚWA wí, “kì yóò sí ẹni tí yóò gbé ibẹ̀.