Jeremiah 50:42 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Wọ́n kó ọrun ati ọ̀kọ̀ lọ́wọ́, ìkà ni wọ́n, wọn kò ní ojú àánú. Ìró wọn dàbí ìró rírú omi òkun; wọ́n gun ẹṣin, wọ́n tò bí àwọn ọmọ ogun. Wọ́n ń bọ̀ wá dojú kọ ọ́, ìwọ Babiloni!
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn o di ọrun ati ọ̀kọ mu: onroro ni nwọn, nwọn kì o si ṣe ãnu: ohùn wọn yio ho gẹgẹ bi okun, nwọn o si gun ori ẹṣin lẹsẹsẹ, nwọn si mura bi ọkunrin ti yio jà ọ logun, iwọ ọmọbinrin Babeli.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wọ́n sì di ìhámọ́ra ọ̀kọ̀ àti ọrun, wọ́n burú wọn kò sì ní àánú. Wọ́n bú bí i rírú omi bí wọ́n ti se ń gun ẹsin wọn lọ. Wọ́n wá bí àkójọpọ̀ ogun láti kọlù ọ́, ìwọ ọmọbìnrin Bábílónì.