Jeremiah 50:44 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
“Wò ó! Bí kinniun tíí yọ ní aginjù odò Jọdani tíí kọlu agbo aguntan, bẹ́ẹ̀ ni n óo yọ sí àwọn ará Babiloni, n óo mú kí wọn sá kúrò lórí ilẹ̀ wọn lójijì; n óo sì yan ẹnikẹ́ni tí ó bá wù mí láti máa ṣe àkóso ibẹ̀. Nítorí ta ló dàbí mi? Ta ló lè yẹ̀ mí lọ́wọ́ wò? Olùṣọ́-aguntan wo ló lè dúró dè mí?
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Wò o, on o goke wá bi kiniun lati wiwú Jordani si ibugbe okuta; nitori ojiji li emi o le wọn lọ kuro nibẹ; ati tani si li ẹniti a yàn, ti emi o yàn sori rẹ̀? nitori tani dabi emi? tani o si pè mi ṣe ẹlẹri? ati tani oluṣọ-agutan na ti yio le duro niwaju mi?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bí i kìnnìún tí ń bú láti igbó Jọ́dánì. N ó lé Bábílónì kúrò ní ilẹ̀ rẹ̀ ní kánmọ́ kánmọ́. Ta ni ẹni àyànfẹ́ náà tí n ó yàn? Ta ló dàbí mi, ta ló dàbí mi, ta ló sì le dojú ìjà kọmí?”