Jeremiah 50:45 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nítorí náà, ẹ gbọ́ ète tí èmi OLUWA pa lórí Babiloni, ati èrò mi lórí àwọn ará Kalidea: A óo kó agbo ẹran wọn lọ tọmọtọmọ; ibùjẹ ẹran wọn yóo sì parun nítorí tiwọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitorina gbọ́ ìmọ Oluwa, ti o ti gba si Babeli: ati èro rẹ̀, ti o ti gba si ilẹ awọn ara Kaldea: lõtọ awọn ti o kere julọ ninu agbo-ẹran: yio wọ́ wọn kiri: lõtọ on o sọ ibugbe di ahoro lori wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí náà, gbọ́ ohun tí OLÚWA sọ nípa Bábílónì ẹni tí ó gbìmọ̀ lòdì sí Bábílónì; n ó sì pa agbo ẹran wọn run.