Jeremiah 50:6 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
“Àwọn eniyan mi dàbí aguntan tí ó sọnù, àwọn olùṣọ́ wọn ti ṣì wọ́n lọ́nà. Wọ́n ń lọ síhìn-ín, sọ́hùn-ún lórí òkè, wọ́n ń ti orí òkè kéékèèké bọ́ sí orí òkè ńláńlá; wọ́n ti gbàgbé ọ̀nà agbo wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn enia mi ti jẹ agbo-agutan ti o sọnu: awọn oluṣọ-agutan wọn ti jẹ ki nwọn ṣina, nwọn ti jẹ ki nwọn rìn kiri lori oke: nwọn ti lọ lati ori oke nla de oke kekere, nwọn ti gbagbe ibusun wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Àwọn ènìyàn mi ti jẹ́ àgùntàn tí ó sọnù, àwọn olùṣọ́ àgùntàn wọn ti jẹ́ kí wọn sìnà, wọ́n ti jẹ́ kí wọn rìn lórí òkè wọ́n ti lọ láti orí òkè ńlá dé òkè kékeré, wọn ti gbàgbé ibùsùn wọn.