Jeremiah 50:9 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nítorí n óo rú ọpọlọpọ orílẹ̀-èdè sókè, láti ìhà àríwá, n óo sì kó wọn wá, wọn óo wá dóti Babiloni, wọn yóo gbógun tì í. Ibẹ̀ ni ọwọ́ wọn yóo ti tẹ̀ ẹ́, tí wọn óo sì fogun kó o. Ọfà wọn dàbí akọni ọmọ ogun, tí kì í pada sílé lọ́wọ́ òfo.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori, wò o, emi o gbe dide, emi o si mu apejọ awọn orilẹ-ède nla lati ilẹ ariwa wá sori Babeli: nwọn o si tẹgun si i, lati ibẹ wá li a o si ti mu u: ọfa wọn yio dabi ti akọni amoye; ọkan kì yio pada li asan.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí pé èmi yóò ru, bẹ́ẹ̀ ni èmi yóò gbé sókè sí Bábílónì àwọn orílẹ̀ èdè ńlá láti ilẹ̀ àríwá. Wọn yóò gba àyà wọn lẹ́gbẹ́ rẹ̀; Láti àríwá wá, à ó sì mú ọ. Ọfà wọn yóò dàbí ọfà àwọn akọni alákíkanjú tí wọn kì í wà lọ́wọ́ òfo