Jeremiah 51:11 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ẹ pọ́n ọfà yín! Ẹ gbé asà yín! Nítorí OLUWA ti ru ẹ̀mí àwọn ọba Media sókè, nítorí pé ó ti pinnu láti pa Babiloni run. Ẹ̀san OLUWA ni, ẹ̀san nítorí tẹmpili rẹ̀ tí wọ́n wó.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Pọ́n ọfa mu: mu asà li ọwọ: Oluwa ti ru ẹmi awọn ọba Media soke: nitori ipinnu rẹ̀ si Babeli ni lati pa a run, nitoripe igbẹsan Oluwa ni, igbẹsan fun tempili rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Lọ ọfà wa kó mú, mú apata! OLÚWA ti ru Ọba Médíà sókè, nítorí pé ète rẹ̀ ni láti pa Bábílónì run. OLÚWA yóò gbẹ̀san, àní ẹ̀san fún Tẹ́ḿpìlì rẹ̀.