Jeremiah 51:16 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nígbà tí ó bá sọ̀rọ̀, ojú ọ̀run yóo kún fún alagbalúgbú omi, ó sì ń mú ìkùukùu gòkè láti òpin ilẹ̀ ayé. Ó dá mànàmáná fún òjò, ó sì mú ìjì jáde láti inú ilé ìṣúra rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbati o ba san ãrá, ọ̀pọlọpọ omi ni mbẹ li oju ọrun; o si mu kũku goke lati opin aiye wá, o dá manamana fun òjo, o si mu ẹfũfu jade lati inu iṣura rẹ̀ wá.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí ará omi ọ̀run hó ó mú kí òfùrufú ru sókè láti ìpẹ̀kun ayé. Ó rán mọ̀nàmọ́ná pẹ̀lú òjò, ó sì mú afẹ́fẹ́ jáde láti ilé ìṣúra rẹ̀.