Jeremiah 51:2 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
n óo rán ìjì líle kan sí Babiloni, ìjì náà yóo fẹ́ ẹ dànù bí ìyàngbò ọkà yóo sì sọ ilẹ̀ rẹ̀ di ahoro, nígbà tí wọ́n bá gbógun tì í yípo, ní ọjọ́ ìpọ́njú.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Emi o si rán awọn alatẹ si Babeli, ti yio fẹ ẹ, nwọn o si sọ ilẹ rẹ̀ di ofo: nitori li ọjọ wahala ni nwọn o wà lọdọ rẹ̀ yikakiri.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èmi yóò rán àwọn àjèjì ènìyàn sí Bábílónì láti ba ilẹ̀ jẹ́, wọn yóò ṣe àtakò rẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà ní ọjọ́ ìparun rẹ̀.