Jeremiah 51:24 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
OLUWA ní, “Níṣojú yín ni n óo fi san ẹ̀san fún Babiloni, ati gbogbo àwọn tí wọn ń gbé Kalidea, fún gbogbo ibi tí wọ́n ṣe sí Sioni; èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn emi o si san fun Babeli ati fun gbogbo awọn olugbe Kaldea gbogbo ibi wọn, ti nwọn ti ṣe ni Sioni li oju nyin, li Oluwa wi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Ní ojú rẹ, èmi yóò san án fún Bábílónì àti gbogbo àwọn olùgbé inú rẹ̀ fún gbogbo ibi tí wọ́n ti ṣe ní Síónì,” ni OLÚWA wí.