Jeremiah 51:26 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Wọn kò ní rí òkúta kan mú jáde ninu rẹ, tí eniyan lè fi ṣe òkúta igun ilé; tabi tí wọn lè fi ṣe ìpìlẹ̀ ilé, ń ṣe ni o óo wó lulẹ̀ títí ayé. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ki nwọn ki o má le mu okuta igun ile, tabi okuta ipilẹ ninu rẹ, ṣugbọn iwọ o di ahoro lailai, li Oluwa wi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
A kò ní mú òkúta kankan láti ọ̀dọ̀ rẹ̀ lò gẹ́gẹ́ bí igun ilé tàbí fún ìpínlẹ̀ nítorí pé ìwọ yóò di ahoro títí ayé,” ní OLÚWA wí.