Jeremiah 51:27 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
“Ẹ ta àsíá sórí ilẹ̀ ayé, ẹ fun fèrè ogun láàrin àwọn orílẹ̀-èdè; kí àwọn orílẹ̀-èdè múra láti gbógun tì í, ẹ sì pe àwọn ìjọba jọ láti dojú kọ ọ́; àwọn ìjọba orílẹ̀-èdè bíi Ararati, Minni, ati Aṣikenasi. Ẹ yan balogun tí yóo gbógun tì í; ẹ kó ẹṣin wá, kí wọn pọ̀ bí eṣú.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ẹ gbe asia soke ni ilẹ na, fọn ipè lãrin awọn orilẹ-ède, sọ awọn orilẹ-ède di mimọ́ sori rẹ̀, pè awọn ijọba Ararati, Minni, ati Aṣkinasi sori rẹ̀, yàn balogun sori rẹ̀, mu awọn ẹṣin wá gẹgẹ bi ẹlẹnga ẹlẹgun.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Gbé àṣíá sókè ní ilẹ̀ náà, fọn ipe láàrin àwọn orílẹ̀ èdè! Pèṣè àwọn orílẹ̀ èdè sílẹ̀ láti bá jagun, pe àwọn ìjọba yìí láti doju kọ ọ́, Árárátì, Mínínì àti Ásíkẹ́nì. Yan olùdarí ogun láti kọlù ú, rán àwọn ẹṣin síi bí ọ̀pọ̀ eṣú.