Jeremiah 51:29 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Jìnnìjìnnì bo gbogbo ilẹ̀ náà, wọ́n wà ninu ìrora, nítorí pé OLUWA kò yí ìpinnu rẹ̀ lórí Babiloni pada, láti sọ ilẹ̀ náà di ahoro, láìsí ẹnìkan kan ninu rẹ̀ mọ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ilẹ yio si mì, yio si kerora: nitori gbogbo èro Oluwa ni a o mú ṣẹ si Babeli, lati sọ ilẹ Babeli di ahoro laini olugbe.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ilẹ̀ wárìrì síhìn ín sọ́hùn ún, nítorí pé ète OLÚWA, sí Bábílónì dúró láti ba ilẹ̀ Bábílónì jẹ́ lọ́nà tí ẹnikẹ́ni kò ní lè gbé inú rẹ̀ mọ́.